Anatoliy Makosov

From TON Wiki (Yo)

Antoliy Makosov je oludarí ìmọ̀-ẹ̀rọ ninu Ńẹtíwọ́ọ̀kì Gbogbo Ènìyàn (TON)

Inagije: tolya-yanot

Anatoliy Makosov
Anatoliy Makosov

Antoliy Makosov jẹ́ sófítíwía dìvẹ́lọ́pà àgbà ati ọkan ninu awọn olupilẹṣẹ TON, eyi ti o je iṣẹ́ ọpọlọ ti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ laarin ara rẹ ati Kirill Emelyanenko. O tun ni iriri ninu  ìṣẹ̀dá geemu (ohun isere t’ori ẹ̀rọ ayára bi àṣá).

Iṣẹ́-ṣíṣe

Ìbá-ṣiṣẹ́ Pẹ̀lú TON

Bi o ṣe n ṣiṣẹ bi olupilẹṣẹ software ni ọdun 2019, o bẹrẹ sii kopa ninu awọn idije siseto Telegram ni akoko ọfẹ rẹ ti o si gba orisirisi ebun ninu m'ẹwa l'áàrín m'ọ́kànlá ninu wọn. Niwọn igba ti diẹ ninu awọn idije wọnyi ti jẹ́ nípa TON blockchain, wọn funun ni aye lati ṣe ajọṣepọ pẹlu awọn abinibi on’ímọ̀ ẹ̀rọ miiran, ọkan ninu wọn ni Kirill Emeliyanenko, olutọpa kan naa ti o kà’wé gb'oyè dókítà ni fisiksi ati mathimatiki.

Telegram ni lati da iṣẹ duro lori TON nitori awọn ifiyesi lati ọ̀dọ̀ awọn Ìgbìmọ̀ l'ẹ́yìn Ìpàṣípàrọ̀ Owó àti ohun iyebíye mìíràn (SEC), ṣugbọn Antoliy ati Kirill tẹsiwaju iṣẹ lori TON nitori wọn ri aanfani pupo ninu ise agbese naa.

Itẹramọṣẹ won lo fàá tí àwọn alábaṣiṣẹ́ mìíràn fi sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn, eyi ti o yọrí sí ìdásílẹ̀ TON Foundation.

Ipa Lọwọlọwọ

Lọwọlọwọ o jẹ okan ninu ẹgbẹ ti n mojuto TON, n’ibi ti o ti dojukọ nẹtiwọọki yi lati rii daju pe o duroṣinṣin ninu aabo nipasẹ iṣẹ lori awọn eroja pataki bii awọn noodu, awọn kompaila, awọn simat kontrati ati awọn iṣẹ pataki miiran bii didanwo awọn paati pataki ati ayẹwo awọn imudojuiwọn ṣaaju awọn idasilẹ.

Awọn Iṣẹ Miiran

  • Makosov ṣiṣẹ bi sófítíwía dìvẹ́lọ́pà apa oníbàarà ni BDdirect (2011-2013) ati Crazy Panda (2013-2014)
  • Oun ni Oludasile The Coding Studio nibi ti o ti wa ni ipo Olóyè Òṣìṣẹ́ On'ímọ̀ Ẹ̀rọ̀.

Ni May ọdún 2023, Antoliy Makosov kopa ninu ifọrọwanilẹnuwo, nibi ti o ti sọ wipe ibi-afẹde ti TON ni lati fun ọpọlọpọ eniyan ni agbaye ni aanfani lati lo owo kiripito-“Apamọwọ kiripito ni gbogbo apo”. Gẹgẹ bi iwadi TripleA ni odun 2023, 4.2% pere ninu gbogbo olugbe agbaye lo n gba cryptocurrency lọwọlọwọ.

Àwọn Ọ̀nà Àsopọ̀

  1. https://t.me/contest
  2. https://ton.foundation/en
  3. https://github.com/tolya-yanot
  4. https://www.npmjs.com/~tolyayanot
  5. https://tonwiki.space/wiki/The_Open_Network
  6. https://triple-a.io/cryptocurrency-ownership-data
  7. https://blog.ton.org/interview-with-anatoly-makosov
  8. https://www.zoominfo.com/p/Tolya-Yanot/6006975772