Telegram Stars

From TON Wiki (Yo)

Telegram Stars

Telegram Stars

Telegram Stars jẹ́ owó abẹ́nú Telegram tí wọ́n fi ń sanwó àwọn ọjà àti iṣẹ́ oní-nọ́ḿbà ní orí Telegram.

Gbajúgbajà ìkànnì àtẹ̀jíṣẹ́ Telegram fí ààyè gba àwọn olùmúlò láti bá ara wọn sọ̀rọ̀ nìkan kọ́, sùgbọ́n làti sanwó nínú ètò aládàáṣiṣẹ́ àti ohun èlò kékeré. Ìfihàn Telegram Stars mú sísanwó dèrò nípa jíjẹ́kí ó rọrùn.

Ìtàn

A fi Telegram Stars lọ́lẹ̀ ní Ìgbà Ooru ní ọdún 2024. Pavel Durov, olùdásílẹ̀ Telegram, náà sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí a se nílò Stars ní ojúòpó Telegram re.

Ìdí tí a fi dá Stars sílẹ̀ ni láti wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìbéèrè Apple ati Google láti lo ètò sísanwó ti inú ohun èlò láti yàgò fún dídínà ohun èlò kékeré àti ètò aládàáṣiṣẹ́. Ní ìdáhùn, Telegram dá Stars sílẹ̀ láti gba olùmúlò láàyè láti ra àwọn ọjà àti iṣẹ́ oní-nọ́ḿbà láì rú òfin àwọn ìbéèrè Apple ati Google.

Àwọn Ẹ̀yà Tó Ṣe Kókó

Telegram 10.14.1 ṣe àfikún ẹ̀yà àtirà àwọn ọjà oní-nọ́ḿbà nípa lílo Stars — àwọn olùmúlò le ra sitika, ṣ’èdá àwòrán àti eré.

Àwọn ohun èlò kékeré nínú Telegram ti ní ẹ̀yà tí a le sanwó fún tàbí àkóónú tí a le rà nípa Stars. Eléyìí ṣínà àwọn ànfàní tuntun fún àwọn onídàgbàsókè ohun èlò kékeré ti Telegram. A tín ṣe àmúlò Telegram Stars nínú àwọn ohun èlò kékeré bíi Gatto, Major, Catizen, pẹ̀lú àwọn ohun èlò mìíràn tí àn ṣe ìmúdójúìwọ̀n fún láti ṣe àtìlẹ́yìn fún ètò ìsanwó náà.

Ẹ̀yà kan tún wà fún gbígbé àkóónú tí ó lówó lórí jáde: àwọn olùmólù yóò díye lé wíwo àwọn fáìlì mídíà tí yóò ṣeéwò lẹ́yì tí a bá sanwó. Àṣàyàn yí fi ààyè gba àwọn olùdásílẹ̀ àkóónú láti pa Stars tí wọn ó yípadà sí Toncoin pẹ̀lú owó díẹ̀ nípa Fragment.

Telegram tún ṣe ìdàgbàsókè ẹ̀yà tuntun tí yóò fààyè gba àwọn olùmúlò láti le lo Stars láti fèsì sí àwọn àtèjáde nínú àwọn ojúòpó.

Nítorí náà, Telegram Stars mú àfikún bá ìwúlò ohun èlò Telegram, ó jẹ́kí ó jẹ́ ìkànnì fún ìbánisọ̀rọ̀ nìkan kọ́, ṣùgbọ́n fún kárà kátà.

Èrè Fún Àwọn Onídàgbàsókè

Telegram fi ààyè gba àwọn onídàgbàsókè láti ná Stars tí wọ́n pa lórí ìpolówó nínú ìkànnì náà. Èyí túmò sípeé àwọn onídàgbàsókè le polówó ohun èlò àti àkóónú pẹ̀lù owó díẹ̀ nígbàtí Telegram ti dínwọ́ owó tóyẹ kán san súnmọ́ òdo.

Fún àwọn olùmúlò, owó lórí rírà pèlú Stars jẹ́ ó pọ̀jù ìdá máàrún nínú ọgọ́rùn.

Telegram tún fún àwọn onídàgbàsókè láàyè sí àpéjọ àwọn olùmúlò tólé ní 950 millionu ènìyàn. Eléyìí ṣí ààyè sílẹ̀ fún pípín àti fífi owó lé ohun èlò àti àkóónú. Pẹ̀lú àwọn olùmúlò tó pọ̀, àwọn onídàgbàsókè le fikún àwọn olùgbọ́ àti owó àgbàwọlé nípa iṣẹ́ tí a sanwó fún nínú ohun èlò kékeré àti ètò aládàáṣiṣẹ́ ti Telegram..

Gatto

Àpẹrẹ Fún Lílò

Ọ̀kan nínú àwọn ohun èlò kékeré tón lo Telegram Stars ni Major. Nínú ohun èlò yí, àwon olùmúlò yín ipò wọn sókè nípa ríra Stars ní àkópọ̀ 1000 sí 25,000 àti píparí àwọn iṣẹ́ àkànṣe.

@Call náà ńlo Telegram Stars. Lára àwọn ẹ̀yà ohun èlò kékeré yí ni ìṣàkóso ètò àti kíkọ́ ọ̀nà àsopọ̀ fún ìpàdé orí ayélujára. Àwọn olùmúlò le ra ìsalábàápín pẹ̀lú Stars lati lè rí ìpàkíyèsí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti ètò aládàáni. Ohun èlò yí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Google Calendar fún ìrántí.

Gatto jẹ́ ohun èlò kékeré míìràn tí ó ńlo Telegram Stars. Ó jẹ́ ohun ọ̀sìn àfọwọ́se tó dàbí Tamagotchi níbi tí àwọn olùmúlò ti ń tọ́jú àwọn ìṣẹ̀dá àfojúinúní tí à ńpè ní Gattomons. Nínú Gatto, o lè lo Stars láti ra ọjà oní-nọ́ḿbà bíi ẹyin Gattomon, aṣọ eranko ọ̀sìn ati tíkẹ́ẹ̀tì àrà ọ̀tọ̀.


Lílò ìmọ̀-èrọ Telegram Stars

Telegram ńse API fún àwọn ètò aládàáṣiṣẹ́, èyí tó gba àwọn olùtàjà láàyè láti gba owó fún ọjà àti iṣẹ́ tààràtà nínú alátẹ̀jísẹ́ nípa akanda rìsíìtì. Àwọn rìsíìtì yí seé rán sí ìtàkurọ̀sọ, pẹ̀lú ẹgbẹ́ àti ojúòpó àti pé wọ́n ní bọ́tìnnì ìsanwó tí yóò gbé ojú ẹwẹ́ ìsanwó jáde nínú ohun èlò náà. Gbogbo owó yóò jẹ́ sísan pẹ̀lú Telegram Stars nìkan.

Láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú API yí, o nílò láti ṣe ìforúkọsílẹ̀ ẹ̀yà aládàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú @BotFather, lẹ́yìn èyí tí ẹ̀yà aládàáṣiṣẹ́ yóò le ṣe ìgbéjáde àti ìfiránseẹ́ àwọn rìsíìtì, àti láti ṣe ìlànà gbígba owó.

Ìlànà rírà Telegram Stars

Láti ra Stars, àwọn olùmúlò le lo ìlànà ìsanwó abẹ́nú ti Google Play tàbí ti App Store, nípasẹ̀ @DurgerKingBot, àti nípasẹ̀ @PremiumBot.

Stars wà fún títà ní ọlókan ọ̀jọ̀kan iye láti 50 sí 2500 ẹyọ, iye owó ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó dá l’órí agbègbè olùmúlò àti ọ̀nà tí ó fẹ́ gbà ràá.

Nípasẹ̀ App Store àti Google Play:

  1. Nínú ohun èlò Telegram: lọ sí «Settings» → «Telegram Stars».
  2. Mú iye Stars tí o nílò.
  3. Parí iṣẹ́ yí nípasẹ̀ ìlànà ìsanwó abẹ́nú ti the App Store tàbí Google Play.

Nípasẹ̀ @PremiumBot:

  1. Sí ìtàkurọ̀sọ pẹ̀lú @PremiumBot nínú ohun èlò Telegram.
  2. Tẹ̀lé àwọn ìtọ́sọ́nà ètò aládàáṣiṣẹ́ láti mú iye Stars àti láti parí rírà.

Nípasẹ̀ @DurgerKingBot:

  1. Nínú ohun èlò Telegram, sí ìtàkurọ̀sọ pẹ̀lú @durgerkingbot, tẹ bọ́tìnnì «Start» láti bẹ̀rẹ̀ rẹ̀.
  2. Lẹ́yìn tí ètò aládàáṣiṣẹ́ bá ti dáhùn, mú àṣàyàn «Order Food».
  3. Mẹ́nù yóò yọ, abala akara òyìnbó yóò wà lókè ní apá òsì. Tẹ bọ́tìnnì «Buy» aláwò ewéko.
  4. Èyí yíò ṣí ménù míràn níbi tí àṣàyàn láti ra Stars yíò wà.

Nípasẹ̀ Fragment:

Stars seé rà ní ibi ìtajà Fragment pẹ̀lú Toncoin.

Lórí ayélujára Fragment, táàbù wà fún Stars, àwọn olùmúlò mú iye Stars tí wọ́n fẹ́ rà àti orúkọ olùmúlò Telegram tí wọ́n fẹ́ rà Stars fún, ìkànnì náà yíò gbé àwòrán ìrísí olùlò Telegram náà jáde, wọ́n ó sì sanwó nípasẹ̀ Toncoin lórí àwọn ohun èlò àpamọ́wọ́ tí Ton ń bá ṣiṣẹ́.

Ọ̀nà Àsopọ̀

  1. https://telegram.org/tos/stars
  2. https://telegram.org/blog/telegram-stars
  3. https://telegram.org/blog/mini-app-bar-paid-media-and-more