The Open Network

From TON Wiki (Yo)
TON Logo

The Open Network (TON) jẹ nẹ́tíwọ́ọ̀kì fún gbogbo ènìyàn lori ẹ̀rọ ígbàlódé tí à ń pè ní blockchain Layer 1, èyí tí ó dá lórí ìmọ̀-ẹ̀rọ lati Telegram. O jẹ nẹtiwọọki tí a gbé kalẹ̀, tí a sì ń ṣè ìtọ́jú rẹ̀ nipasẹ àwùjọ awọn olumulo ati awọn onímọ̀ ẹ̀rọ ayélujára. Wọ́n wà ní ìṣọ̀kan nípasẹ̀ àwọn iye tí ó wọ́pọ̀ - Intanẹẹti ọ̀fẹ́ tí a pín fún gbogbo ènìyàn, èyítí awọn imọ-ẹrọ ti ko si l'àbẹ́ ìṣàkóso ẹnìkan t'àbi ẹgbẹ́ ati awọn owo ami crypto jẹ apa kan. Iṣẹ awọn onímọ̀ ẹ̀rọ ni lati sọ blockchain di ohun tí gbogbo ayé ń lò. Lati jẹ ki iraye si awọn anfani rẹ rọrun bi ohun elo ti o wọ́pọ̀ lori foonu rẹ.

Iṣẹ́ tí TON pinnu lati ṣe ni lati ṣẹ̀dá àti lati lo àwọn ẹ̀rọ ígbàlódé tuntun tí yíò fi àyè gba pàṣípaàrọ̀ owó, ìmọ̀, àti ìrònún fún gbogbo ènìyàn l'ọ̀fẹ́. Àwọn ìmọ̀-ẹ̀rọ ti a ṣẹ̀dá lati dáàbòbo ominira, asiri, ati ẹtọ gbogbo eniyan, lati ṣe aye yi ni iwọntunwọnsi diẹ sii ati ibi iṣakoso ara ẹni. Ọ̀kan nínú àwọn ibi-afẹ́dé ti iṣẹ́ àkànṣe náà ni lati mú àwọn cryptocurrency de ọdọ ọkẹ àìmọye awọn olùmúlò, ati pe o ṣeun si iṣẹ ṣiṣe rẹ o jẹ ifọwọsi ni idanwo gbangba ni oṣù k'ẹwa, ọjọ kankànlélọ́gbọ̀n, ọdún 2023 bi blockchain ti o yara ju ni agbaye nipasẹ ṣiṣakoso lati ṣe ilana awọn iṣowo 108,409 fun iṣẹju keji.

Ìtàn

Ìkéde nípa Telegram Open Networkkọ́kọ́ w'áyé ni ọdún 2017 gẹ́gẹ́ bi ìpilẹsẹ̀ lati gbé blockchain tí ó k'ójú òṣùwọ̀n kalẹ̀. Ibi-afẹde naa ni lati bori awọn ìdíwọ́ tí ó wà nínú àwọn blockchain tí ó ti wà tẹ́lẹ̀, kí a sì fi aàyè gba gbogbo ènìyàn ní àgbàńlá aiyé lati lòó.

Ni ọdun 2018, Telegram ṣe aṣeyọrí ní títa tókìnì rẹ̀ n'íkọ̀kọ̀ lati ṣe ìnáwó ìdàgbàsókè ti Telegram Open Network. Sibẹsibẹ, iṣẹ́ àgbéṣe na d'ojú kọ ìlànà àti àwọn ìtaláyà òfin, tí ó yọrí sí àwọn ìdádúró àti àwọn àríyànjiyàn òfin. Ní ìparí rẹ̀, ní ọdún 2020, Securities and Exchange Commission (SEC) ní ìlú Amẹ́ríkà fi ipá mú Telegram lati fagilé ìfilọ́lẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe naa nitori awọn ọran ofin.


Pẹ̀lú àwọn ìfàsẹ́yìn wọ̀nyí, Telegram fi kóòdù orísun TON sílẹ̀ fún àwon on'ímọ̀ sọ́fítíwià nínú àwùjọ lati tẹsiwaju idagbasoke ise naa.


Ní oṣu k'arun ọjọ́ kọkàn dín l'ọ́gbọ̀n, ọdún 2020, àwùjọ àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ tío dádúró, àwọn olùfọwọ́sí, àwọn olùborí nínú àwọn idije Telegram àti gbogbo àwọn tio fẹ́ràn crypto kede ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ lori iṣẹ àkànṣe naa.


Ẹgbẹ naa tẹ̀síwájú lati ṣetọju ati idagbasoke nẹtiwọki testnet2, èyítí Telegram ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ni oṣù kọkànlá ọjọ́ kẹẹ̀dógún, ọdún 2019.


Ni Oṣu Karun ọdun 2021, agbegbe ti dibo lati tunruko nẹtiwọọki testnet2 si mainnet. Ati orukọ «NEWTON» yipada si «TON Foundation», eyiti o di agbegbe ti kii ṣe èrè, ti o pinnu lati dagbasoke siwaju ati atilẹyin nẹtiwọọki naa.

Ní oṣù kẹfà ọjọ́ kọkàn dín l'ọ́gbọ̀n, ọdun 2021, ẹgbẹ́ Telegram gbà lati yọ̀nda ton.org ati akọọlẹ GitHub fun àwọn àwùjọ tó ń ṣiṣẹ́ lori Nẹtiwọọki fún gbogbo ènìyàn ní ìdáhùn sí lẹ́tà.


Ni oṣu kẹjọ, ọjọ kẹsan, ọdun 2021, EXMO kede tita Toncoin cryptocurrency lori ẹ̀rọ rẹ̀, èyítí ó di owó abínibí ti TON. O jẹ lilo fun awọn ìṣòwò nẹ́tíwọ́ọ̀kì, awọn ere tabi awọn ikójọpọ̀ lori awọn ọjà ti a ṣẹda lori TON blockchain. Toncoin wa laarin awọn owó mẹ́ẹ̀dógún to ṣíwájú lori CoinMarketCap ati CoinGecko.

Ni oṣu keje, ọjọ kẹfà, ọdun 2020, pinpin fun gbogbo Toncoins ti o wa (98.55% ti ọja lapapọ) bẹrẹ. A gbe àwọn owó naa sinu awọn adehun ọlọgbọn PoW ti olufunni pataki, tio gbigba gbogbo eniyan laaye lati kopa ninu pinpin wọn titi di oṣu karun ọjọ keji din l'ọ́gbọ̀n, ọdún 2022. Gbogbo Toncoins ti o di pinpin ni ojoojumọ́ jẹ́ 200,000 TON.


Ni oṣu kẹsan, ọdún 2023, ni apejọ TOKEN2049, TON Foundation ati Telegram kede ifilọlẹ TON Space, aaye ti kii ṣe itọju ti o fun awọn olumulo ni iṣakoso ni kikun lori awọn ohun-ini oni-nọmba ti o da lori Wallet taara lori Telegram.

Ni oṣu k'ẹwa, ọjọ́ kọkàn lé l'ọ́gbọ̀n, lakoko ti TON k'oju idánwo iṣẹ́ rẹ̀ ni gbangba, TON jáwé olubori ni agbaye fun nọmba awọn iṣowo ti o lagbara lati gbalaye ninu iṣẹju, ti abajade rẹ̀ jẹ́ 108,409 TPS.

Apejọ TON akọkọ, ti wọ́n sọ́ ni The Gateway, waye ni Dubai ni oṣu kọkanla ọjọ k'ẹwà si ikọkànlá, ọdún 2023.


Ni oṣù kini, ọjọ kọkàn din l'ọ́gbọ̀n, ọdun 2024, àkọ́kọ́ eto iwuri fun awọn olumulo TON bẹ̀rẹ̀: The Open League.

TON Blockchain within the Telegram app
TON Blockchain in Telegram App

Ẹ̀rọ ígbàlódé

Hack-a-TON DoraHacks
DoraHacks Hack-a-TON

Ẹgbẹ TON ti ṣe àkíyèsí ní kíkún lati ṣẹ̀dá Blockchain tó kún ojú òṣùwọ̀n lati ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ohun amáyédẹrùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ l'ábẹ́ àkóso gbogbo ènìyàn. Lati ṣe aṣeyọri gbogbo eyi, TON ṣe ipilẹ idagbasoke rẹ lori awọn imọ-ẹrọ wọnyi: Proof-of-Stake ati Shardingfun ìwọ̀n gíga. Ṣíṣẹ̀dá, idagbasoke ati ìmúṣiṣẹ́ awọn smart contract lo ede FunC ati Fift atiTON Virtual Machine (TVM). Gbogbo smart contracts lori TON nṣiṣẹ ni ominira lori TVM. TVM dá l'órí ẹ̀rọ-àkópọ̀, èyí tí ó mú l'ílò rẹ̀ k'ójú òṣùwọ̀n tí ó sì rọrùn.

TON blockchain jẹ́ nẹtiwọki tó ní ipele mẹta:

Ni ipele akọkọ a ni Master chain, eyiti o ṣiṣẹ nitori Proof-of-Stake (PoS) algorithm ti o pèsè ìyára, scalability ati aabo fun nẹtiwọki naa. Master chain yii lo jẹ chain akọkọ ti nẹtiwọọki TON ti o si n ṣiṣẹ lọwọlọwọ. Iyẹn ni wipe, ni gbogbo igba ti a ṣe iṣẹ kan ni TON, ori master chain yi lo ti n ṣẹlẹ̀.


Lẹhinna, ni ipele keji, a ni àwọn Work Chains, eyiti o jẹ awọn chain keji ti o sopọ mọ Master chain. Ọkọọkan ninu awọn Work chains wọnyi le ni eto ti ara rẹ pẹ̀lú awọn ofin ifọkanbalẹ ti o fi ń ṣiṣẹ́, pẹlu oriṣiriṣi akọọlẹ ati awọn adirẹsi kátàkárà, awọn ẹrọ ori intanẹ́tì ti n ṣiṣẹ awọn smart contract ati awọn cryptocurrency, ati bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Gbogbo eyi laisi idaduro lati ni ibamu pẹlu Master Chain; nitorinaa o ni anfani lati ṣisèẹ́ pẹlu rẹ, ati pẹlu ọ̀kọ̀ọkan awọn Work Chains y'oku, lai si wahala kankan.


Nikẹhin, a ni ipele kẹta, eyiti o jẹ Sharding Chains. Sharding Chains jẹ apakan lara Work Chains ti o fun ni scalability, eyi ti o pin iṣẹ naa l'ati jẹ́ kó yá. Ni ọna yii, Scalability TON yoo ga ju eyi ti o wa ni awọn blockchain bii Polkadot tabi Solana lọwọlọwọ. Gbogbo eyi ṣeé ṣe nitori ètò isalẹ-soke ti TON nlo fun awọn shard chain rẹ, eyi ti wọn pe ni Infinite Sharding Paradigm.


TON blockchain jẹ apẹrẹ supercomputer ti a pin kaakiri, tabi «superserver», ti a ṣẹ̀dá lati pese ọpọlọpọ awọn ọja ati iṣẹ ti o ṣe agbega iran Intanẹẹti tuntun ti kò sí l'abẹ́ àkóso eniyan t'abi ẹgbẹ́ kan ṣoṣo.

Tonkeeper Wallet Interface
Tonkeeper Interface

Ìwúlò àti Ọjà t'a Fihàn ní TON

Awọn olupilẹṣẹ le kọ́ awọn ohun elo wọn s'ori blockchain TON fun awọn olùmúlò l'ati le lo wọn ninu igbesi aye wọn l'ójoojúmọ́.


TON blockchain jẹ́ ko ṣeé ṣe lati tọju owo sí inu apamọwọ ara ẹni pẹ̀lú aabo to dájú, laisi alabojuto ati lati fi owó ránṣẹ́ ní èyíkèyí iye, nígbàkúgbà àti níbikíbi tí o bá fẹ́ pẹ̀lú àwọn ìdíyelé tí ó kéré jù. Ó sì tún ṣeé ṣe lati lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èlò ìsọdọ̀tun tí ó dá lórí TON. Ni oṣù kẹ̀ta ọjọ́ kọkàn dín l'ógún, ọdún 2024, àwọn ohun èlò 611 ló ti wà nínú kátálọ́ọ̀gì ohun èlò TON — àwọn olupilẹṣẹ ń lo blockchain tààrà bí agbègbè tí ó ní ààbò lati ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn iṣẹ́ wọn.

Tonkeeper

Èyí jẹ́ àpamọ́wọ́ àkọ́kọ́ (tí à ń fún ra ẹni pamọ́) lati fun àwọn olùmúlò ní àànfàní lati gba Toncoin, tàbí fipamọ́, tàbí firánṣẹ́. O tún lè lo àpamọ́wọ́ náà lati ṣe kátàkárà pẹlu TON Jettons, ati lati ṣe ìtọ́jú, firanṣẹ ati gbígba àwọn ìkójọpọ̀ oní-nọ́mbà ati àwọn NFT miiran. Ìwọ nìkan lo ní iṣakoso ohun ti o wà ninu rẹ, o sí jẹ́ alábojútó fún àṣír àti wọlé sí àpamọ́wọ́ naa.

STON.fi

Èyí jẹ́ ibi tí a ti ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó crypto tí a gbé kalẹ̀ lori blockchain TON, tí ń fúnni ní àwọn idiyele ti o dára jù, ati ìsopọ̀ tààrà pẹ̀lú àwọn àpamọ́wọ́ TON. Ibi pàṣípààrọ̀ naa wa lati ṣe iṣowo Toncoin fun awọn Jettons miiran, stablecoins, wrapped BTC, ETH, ati awọn owó miiran. Ni afikun, ni STON.fi o le pese liquidity lati pawó ni ọpọlọpọ farming pools pẹlu ere ọdọọdún tí à ń pè ní APY.

TON Proxy

TON Proxy jẹ́ aṣojú nẹ́tíwọọki ati anonymizer tí a gbé kalẹ̀ fun TON nodes. Ó dàbí iṣẹ akanṣe Intanẹẹti tí a kò fi ojú rí, tí ó jẹ́ kí ó rọrùn lati ṣẹ̀dá ẹ̀rọ ìgbàlódé tí à ń pè ní decentralized VPN services ati awọn omiiran ti o da lori blockchain gẹ́gẹ́ bí ìdàkejì TOR. Agbára yii ṣe ilọsiwaju aṣiri ori ayélujára ati pe o jẹ ki o rọrun lati ṣẹda awọn ohun elo tí à ń pè ní decentralized applications (DAPPs) tí ó lè jẹ́ ìṣòro díẹ̀ síi fún ìhámọ́. Lati oṣù kẹsan ọjọ́ ọgbóọ̀n, ọdún 2022, TON Proxy ni ibaramu pẹlu HTTP Proxy.

TON DNS

TON DNS, èyí tí a ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ni oṣù kẹfà ọjọ́ ọgbọ̀n, ọdún 2022, ń ṣiṣẹ́ bakanna sí àwọn orúkọ-ìdánimọ̀ lorí ẹ̀rọ ayélujára tí ó ní nkan ṣe pẹ̀lú àwọn owo-iworo crypto miiran, ti o funni ni “.ton” gẹ́gẹ́bí ààyè rẹ̀. Ètò naa ṣe ipinnu awọn orukọ ti o rọrun lati rántí si awọn akọọlẹ, awọn smart contract, awọn iṣẹ, ati network nodes. Iṣẹ́ yii jẹ́ kí ìlànà ìráyè si decentralized applications rọrùn nípa gbígba àwọn olùmúlò láàyè lati lo áwọn orúkọ kúkúrÍú tí ó rọrùn dípò àwọn nọ́mbà-t'álfábẹ́tì tó gùn. Àwọn orúkọ naa tún lè somọ́ àwọn àdírẹ́sì àpamọ́wọ́.

Ibi Ìpamọ́ TON

Ní oṣù kejìlá ọjọ́ kọkàn lé l'ọ́gbọ̀n, ọdun 2022, a ṣe àgbékalẹ̀ ibi ìpamọ́ TON, èyí tí ó jẹ́ ètò ibi ìpamọ́ faili tí gbogbo ènìyàn lè rí. Nípasẹ̀ ibi ìpamọ́ TON, à ń ṣẹ̀dá ètò ibi ipamọ tí à ń pè ní decentralized P2P cloud storage tí yíò ṣe ìtọ́jú data rẹ lori gbogbo nẹtiwọọki naa nípa lílo smart contracts.

Fragment

Fragment jẹ́ ibi ìtajà tí a ti ń ta àwọn orúkọ olùmúlò Telegram tí kò fàyè gba ìdánimọ̀ ati awọn nọmba lori blockchain TON. Laipẹ, a fi rira Telegram premium pẹ̀lú Toncoin kun.

Getgems

Èyí ni ó ṣíwájú nínú àwọn ibi a ti ń ṣe pàṣípààrọ̀ NFT lóríi nẹ́tíwọ́ọ̀kì TON. Àwọn ọgọọgọrun ìkójọpọ̀ NFT ni ó wà lórí ibi ìtajà naa, tí ó lẹ́wà tí ó sì rọrùn lati lò. Laipe, Getgems darapọ̀ mọ́ ìṣípòpadà CNFT, èyí tí ó jẹ́ ọ̀nà tuntun lati ṣẹ̀dá àwọn NFT lọpọlọpọ ní owó tí ó kéré jù, èyítí Nẹtiwọọki TON nìkan ní agbára lati ṣe l'aṣeyọri. Bí o bá fẹ́ lo Getgems, ohun tí o ní lati ṣe ni kí o so àpamọ́wọ́ rẹ níbití o fi àwọn NFT rẹ pamọ́ sí.

TONup Launchpad

Iṣẹ́ tí TONup Launchpad ń ṣe ni lati ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìfilọ́lẹ̀ àwọn iṣẹ akanṣe lori ecosystem TON. Àwọn ohun tí o iduro fun pẹ̀lú ipese awọn iṣẹ bii ìkówójọ, ìṣẹ̀dá àmì, ìdámọ̀ràn, ìpàtẹ, ati fífún awọn onímọ̀ ẹ̀rọ kakiri agbaye l'ágbára lati ṣẹ̀dá lori TON. TONup Launchpad mú àwọn ìdènà wọ̀nyí kúrò nipa gbígba àwọn iṣẹ́ àkànṣe n'ímọ̀ràn imọ-ẹrọ ati titaja lati ṣe iranlọwọ fún ìgbélárugẹ.

TON Lending Protocol

Èyí jẹ́ ọjà tí a gbékalẹ̀ nipasẹ olùṣàkóso ìdókò-òwò ti ibi pàṣípààrọ̀ MEXX, èyítí ń gba àwọn olùmúlò láàyè lati yáwó pẹ̀lú ohun àfidúró ní TON.

TON Browser

Ọkan ninu awọn ìkéde tí ó dára jùlọ ni ìgbèrò fun browser tuntun tí ó dá lori TON, èyítí a gbèrò lati ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 2024. Yóò ní ìbáraẹniṣepọ̀ pẹ̀lú gbogbo awọn iṣẹ́ àkànṣe ori TON.

Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ L'aarin TON ati Telegram

Àwọn iṣẹ́ àkànṣe méjèèjì ti súnmọ́ ara wọn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ ní àwọn oṣù tó kọjá láìpẹ́. Fún TON, ó ṣe pàtàkì pé kí Blockchain TON ati Telegram Super App fúnni ní àwọn iṣẹ́ àkànṣe gidi lati fa àwọn olumulo Web2 wá sí web3 nípa ìpèsè àwọn ọjà ojúlówó ní ìbámu sí àwọn ìwúlò wọn.


Ni oṣù kọkànlá ọjọ́ k'ẹwa, ọ́dun 2023, ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé tó dìtàn fún àwùjọ TON, tí a pè ní The Gateway, èyítí ó wáyé ní ìlú Dubai nibi ti àwọn ẹni 500 ti péjọ, bí àwọn olùmúlò, àwọn onímọ̀-ẹ̀rọ (dìfẹ́lọ́pà) àti àwọn olùdókòwò tí ó fẹ́ tẹ̀síwájú lati lo ìmọ̀tuntun fi ṣẹ̀dá lori TON, pẹ̀lú ìran lati dé ọ̀dọ̀ gbogbo eniyan nípasẹ̀ àjọṣepọ̀ ati ìsúnmọ́óọ rẹ̀ pẹ̀lú Telegram.


Ní ìṣáájú sí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, TON Blockchain ṣàṣeyọrí ìlọsíwájú pàtàkì, gẹ́gẹ́bí iyọrisi Guinness World Record fún nọ́mbà àwọn ìṣòwò tí ó ga jùlọ ní Blockchain kan, èyítí ó pọ̀ ju nọ́mbà àwọn àkanti TON àti àwọn àpamọ́wọ́ ní ìlọ́po ogójì ní ìbátan sí ọdún 2021 - èyítí ó fi TON sí ojú àwọn ọgọọgọ̀rún àwọn olùdókòwò, tí ó sì fi TON cryptocurrency ipò kẹwa ní aarin àwọn cryptocurrency tóní ìṣòwò ọjà tí ó ga jùlọ.

Àpamọ́wọ́ TON Space

Ifilọlẹ àpamọ́wọ́ tí à ń pè ní TON Space fún ìlò ara ẹni lórí Telegram lati inú àṣàyàn àkọ́kọ́ jẹ́ àṣeyọrí ńlá fún TON, nítorí wípé ó lè j'ànfàní àwọn olùmúlò Telegram tí ó ju mílíọ́nù 900, tí ó lé lo àpamọ́wọ́ naa nírọ̀rùn, nínú èyítí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn TON Jetton wa.

The Open League

Èyí jẹ́ àkànse èrè ńlá tí ó pín owó tó ju $160M ni Toncoin ní ipele àkọ́kọ́ nikan fún àwọn ẹgbẹ́ tí ó ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn iṣẹ́ àkànṣe lórí TON, tí ó fi kún àwùjọ ati TVL ninu TON.

TON Gaming

Èyí jẹ́ àjọṣepọ̀ kan tí ó ní èrò lati sọ ìṣòwò eré orí ẹ̀rọ ayélujára jí nípa lílo ànfàní awọn olùmúlò Telegram ti wọn jẹ́ 900M, tí ó sì ń se àtìlẹ́yìn àwọn onímọ̀-ẹ̀rọ ní gbogbo ipele ti ìlànà ẹ̀dá eré orí ayélujára.


Ibi-afẹ́dé ní ọjọ́ iwájú yóò jẹ́ lati tẹsiwaju ni ajọṣepọ pẹlu Telegram ti nkọ Telegram Web3 Super App. Eyi yoo ṣe iranlọwọ lati sọ crypto di ohun tí ènìyàn ń lò ní gbogbo agbegbe ní àgbàńlá ayé nípasẹ̀ Telegram Mini Apps.

Àwùjọ

Lati ìpilẹsẹ̀ẹ rẹ̀, iṣẹ́ àkànṣe náà ti ní ìbáṣepọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú àwùjọ rẹ, èyítí ó kópa nínú gbogbo ipele ìdàgbàsókè, tí ó sì tẹsiwaju lati ṣe atilẹyin fun gbogbo ipinnu ti a ṣe lati jẹ́kí TON ecosystem dagba. Ni ọdun 2023, TON ní ìmúgbòrò tí ó tóbi pupọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílọ̀-èdè, a sì ní lati gbé àwọn ohun èló tí ó yàtọ̀ pupọ kalẹ̀ lati ṣe ìyípadà sí Web3. TON ti ṣe dáradára lati fi ararẹ̀ sí ara TOP 10 cryptocurrency pẹ̀lú ìṣòwò ọjà tí ó ga jùlọ, ó sì ń tẹ̀síwájú lati gbé àwọn ìgbésẹ̀ nla tí yoo jẹ́ kó gbé ipò àkọ́kọ́.


TON ni áwọn onímọ́-ẹ̀rọ ti o pọ̀ káàkiri ní gbogbo àgbáyé tí ń ṣiṣẹ́ látọ̀nà jíjìn. Ọmọ ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan tó ṣe gbòógì jẹ alámọ̀dájú gbogbogbò. Ẹnikẹ́ni kò dá ǹkankan sílẹ̀; gbogbo ìmúdójúìwọ̀n si yege ìdánwò nípasẹ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ̀ mẹta, o kere ju; gbogbo ènìyàn ló sì ní àànfàní lati kópa nínú bug bounty.


Lati ọdun 2022, TON ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ìta tí ò dára jùlọ lati ṣàyẹ̀wò kóòdù náà, tí yíò wá ibi tó kù díẹ̀ káàtó sí ninu rẹ: CertiK, Trail of Bits, Hexens, Quantstamp ati awọn miiran.


Bayi, àwọn olórí ẹgbẹ́ tí ń mojuto ǹkan ti ráyé dojúkọ díẹ̀ síi lórí iṣẹ́: node, compiler, system smart contracts ati diẹ ninu awọn infrastructure bi blockchain bridge.

TON ti ní àwọn ẹgbẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ àti àwọn onímọ̀-ẹ̀rọ tó dá dúró tí ó ṣẹ̀dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjà. TON ti di “iṣẹ́-àwùjọ” patapata.

TON ní ètò fífúnnilati ṣe àtìlẹ́yìn àwọn iṣẹ́-àkànṣe tí ó ní ìlérí àti àwọn ojutu tí ó wúlò fún ìdàgbàsókè TON ecosystem.

TON Society

Nẹtiwọọki àwùjọ tuntun tí TON ecosystem ń ṣiṣẹ́ ní Telegram gẹ́gẹ́ bi geo-hubs, ó sì pèsè olùmúlò pẹ̀lú ìdánimọ̀ oní-nọ́mbà àti olókìkí jákèjádò ecosystem, nítorí àwọn àṣeyọrí tí o ṣe nínú ètó ìwúrí tí à ń pé níThe Open League.

Àwùjọ TON ní báyìí ti kọjá àwọn olùmúlò 30M, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn iṣẹ́ àkànṣe bíi Notcoin. Ìrètí wà wípé TON ecosystem yoo dé ọ̀dọ̀ àwọn olùgbọ́ ńlá kan lati mú ìlérí tí a ti ńretí pípẹ́ ṣẹ- crypto lọ́wọ́ọ gbogbo eniyan.

Links

  1. The Open Network website
  2. TON Ecosystem Map
  3. TON Whitepaper — TON Blockchain General Description
  4. TON Virtual Machine — A high-level overview of TON Virtual Machine
  5. English speaking TON Telegram channel
  6. username shop